ÌPÌLẸ̀



Ká ṣiṣẹ́ ká lè jàre ìṣẹ́ la gbọ́ lẹ́nu àwọn baba- ńlá wa,
Ẹni ń ṣiṣẹ́ ń ṣiṣẹ́ kò sí ohun à ti tọ́ka sí fún ìlààgún ìṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru,
Bàbá àgbẹ̀ lọ sóko, gbẹṣu, gbẹ̀gbàdo,
Iṣu ta, àgbàdo yọmọ bọ̀kùàbọ̀kùà,
Inú bàbá àgbẹ̀ dún ùn,
Ó kó irè oko lọ ta lọ́jà,
Bàbá àgbẹ̀ dọ́jà,
Èrò ọjà kọ́ ọ̀ láti rọjà bàbá àgbẹ̀,
Ìrònú dorí bàbá àgbẹ̀ kodò lórí ohun tó fà á tọ́jà òun fi kùtà lọ́jà,
Bàbá àgbẹ̀ ronú lórí ohun tó yíwọ́ tíṣu tó ta fi dòkùtà lọ́jà,
Táwọn èrò ọjà fi kọ̀ láti rọjà bàbá àgbẹ̀,
Bíṣu ti ta, bágbàdo ti yọmọ bọ̀kùàbọ̀kùà,
À wò mọ́jú ni àwọn ará ọjà ń wo àgbàdo tó ta bọ̀kùàbọ̀kùà,
Bàbá àgbẹ̀ ronú, Ó ronú kan ìpìlẹ̀ tó ń tẹ̀ láti gbẹṣu tó ta gbẹ̀gbàdo tó yọmọ bọ̀kùàbọ̀kùà,
Èyí ló jẹ́ kí bàbá àgbẹ̀ lóye pé,
Iṣu tó ta, àgbàdo tó yọmọ bọ̀kùàbọ̀kùà tó di ohun tàwọn ará ọjà ń wò láwò mọ́jú níbá,
Ọ̀nà tí bàbá àgbẹ̀ tọ́ ọ̀ tágbàdo fi yọmọ bọ̀kùàbọ̀kùà kò mọ́,
Afẹ́fẹ́ fẹ́, a rí fùrọ̀ adìẹ, àṣírí iṣu tó ta, àgbàdo tó yọmọ bọ̀kùàbọ̀kùà fún bàbá àgbẹ̀ layé ti rí.

©ABÍYÌKẸ́Ẹ́ AKÉWÌ.

Leave a comment