Èso






Àgbẹ̀ fún irúgbìn sí ilẹ̀,
Kí ó lè sọ èso rere ,
Irú èso wo ni irúgbìn ó so?
Dídùn tàbí kíkan ?
Ṣùgbọ́n ṣáá ,
Gbogbo rẹ̀ dá lórí
Ìgbìyànjú àgbẹ̀,
Nípa sísán ọkọ àti ìtọ́jú irúgbìn àti ewé .

Lẹ́yìn àsìkò díẹ̀ irúgbìn yọ ewé ,
Ewé di igi, igi yọ èso,
Irú èso wo ni igi ó yọ ?
Dídùn àbí kíkan ,
Ìbéèrè fún àgbẹ̀ ,
Ṣé ó fún irúgbìn ní ìtọ́jú tó péye ?

Òbí ni àgbè tí í ṣe ìtọ́jú fún irúgbìn ,
Ọmọ ni irúgbìn ,
Ọmọ ni adùn ayé ,
Bẹ́ẹ̀ ó tún un lè jẹ́ ìdàkejì,
Pàtàkì ni kí òbí kọ́ ọmọ ní ẹ̀kọ́ ,
Ẹ̀kọ́ ìwà rere, ìwà àtàtà
Ẹ̀kọ́ ìgbé ayé ìrọ̀rùn .

Ilé ni ati ń kó ẹ̀ṣọ́ ròde,
Ẹ̀kọ́ rere tí a bá kọ́ ní ilé
Ní a máa múlò ní òde ,
Ọmọ tí a kò kọ́ ní í gbé ilé ti a kọ́ tà,
Ọmọ tí kò ní ẹ̀kọ́ ní í di ìjàngbọ̀n sí àdúgbò ,
Ọmọ tí a kọ kọ́ ní ilé ,
Ní í di ìpáǹle sí ìlú .

Ọmo tí a kọ́ ní i wúlò ní ìlú ,
Ní àwùjọ àti àyíká.
Ọmọ tí a kọ́ ní í di omọlúwàbí
O ní ìwà àtàtà,
Alákíkanjú.

©Al-Kawthar

Leave a comment