Eee! Eee!
Huu!Huu!
Omi lé róró lójú akọni,
Èémí ẹ̀dùn ni wọ́n ń mí kíkan kíkan ,
Isan òun agbára ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ,
Àpaàmúdélé ni kìí jẹ́ ká mọ̀ pé ológbò ń ṣọdẹ,
Iṣẹ́ òórọ̀ òun tọ̀sán lakíkanjú tẹpa mọ́,
Láti lè múnú ẹbí dùn ,
Àágùn ń ṣẹ́ kíkankíkan ,
Ìlàkàkà ni dúníyàn ń gbà ,
Nítorí à ti jàre ebi òun ìṣé,
Adìẹ ń làágùn,ìyẹ́ ara rẹ̀ ò jẹ́ á mọpa tádìẹ ń sà,
Kólú gbani,Èdùà ràn wá ṣe !
Òjò ìbùkún la bẹ̀bẹ̀ fún,
Káyé ó lè dẹ tẹrú tòmọ.
@Abíyìkẹ́ẹ́akéwì