SÙÚRÙ

By: Awotunde Dorcas 

Sùúrù lè se òkúta jiná,

Ẹ gbọ́, ṣe lóòótọ́ ni?

Rárá o,

Àwọn àgbà fi sọ pé, sùúrù ò gbọdọ̀ tán nílé oní sùúrù,

Akẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ gboyè,

Ẹ gbọ́ kí ni yóò kọ́kọ́ ni?

Ẹ sọ pé sùúrù,

Mo fẹ́ máa fi iṣẹ́ ọwọ́ jẹun,

Pẹ̀lú sùúrù náà ni,

Àbí, ó ó ṣà kọ́kọ́ kọ́ṣẹ́ gbàyọ̀ǹda lọ́wọ́ ọ̀gá ná,

Kágbàdo tó ta lóko,

Sùúrù làgbẹ̀ ń ní,

Ẹ̀dá tí ò bá gòkè láyé,

Yóò kọ́kọ́ fi sùúrù tẹ̀ ẹ̀ jẹ́jẹ́,

Ààrẹ wa kúkú ti sọ̀rọ̀ tán,

Ó ní “ẹ lọ fọkàn balẹ̀”

Kò kúkú paró,

Ẹ̀dá tó bá ń joyin inú àpáta,

Pẹ̀lú iṣẹ́ òun sùúrù ni,

Ẹ lọ fọkàn balẹ̀,

Ẹ lọ ní sùúrù,

Ẹ lọ mú sùúrù,

Oní sùúrù lè sohun gbogbo tán láyé,

Kìí ṣàwàdà o jàre,

O fẹ́ dáwọ́ lé ohun kan láyé bí?

Kọ́kọ́ lọ kọ́ bí Wọ́n tí ń ní sùúrù.

Leave a comment