OWÓ

By: Awotunde Dorcas

Photo credit: Shutterstock



Owó àpèkánukò,
Owó bóun ò bá sí nílé,
Kéèyàn má ṣe ohunkóhun,
Owó tó ń mú kí bàbá máa wa ọkọ̀ nínú yàrá,
Á ní “ùhn ùhn ùhn”,
Owó ló ń mú kí ìyáálé ilé máa ké bí òròmọ adìyẹ,
Á ní “ṣé ò sí o?”
Àìsí owó ló ń mú kí akẹ́kọ̀ọ́ ó máa pòṣé ṣààràṣà,
Á ní “ìwé ọ̀hún ò tiẹ̀ wọrí”,
Owó tó ń mú kí baálé ilé rọ̀ bíi ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀,
Òhun ló mú ọmọ ẹlòmíràn ṣìwàwù,
Wọ́n á ní “money is speaking”,
Ẹ ẹ̀ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn,
Owó dára ní tòótọ́,
Bẹ́ẹ̀ sì ni, ó lójú ohun tówó ò le ra,
Owó kúkú dùn-ún ná,
Bẹ́ẹ̀ owó ta rí lọ́nà ẹ̀tọ́ a máa fini lọ́kàn balẹ̀,
Nítorí náà, ẹ rọra sáré owó,
Ẹ rọra sáré ọ̀na ọlà,
Àbí kí ni àǹfààní owó tí kò ní àlàáfíà nínú?
Kí ni àǹfààní owó tí ìnira ń bẹ nínú ẹ̀?
Kí ni ìwúlò owó tí ń gé ọjọ́ ẹni kúrú?
Àròyé ò kúkú kún kágbọ̀n,
Ìmọ̀ràn mi ò ju bíńtín lọ,
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ọra sáré owó.

Leave a comment